HYMN 675
1. AWON omode s’eka wewe
at’imope s'ona
Won si nke, Hosana
Eyi ni orin segun t’a ko wonu
Jerusalem
Hosana! Hosana!
Egbe: Eyi l'Omo nla Dafidi ati Oba Israeli
Ogun ketekete lo fun igbala omo
eniyan
Hosana! Hosana!
Hosana si Omo Dafidi.
2. Awon agbagba gbiyanju lati
pa won lenu mo
Won tun nke Hosana
B‘awon wonyi pa enu won mo
okuta yo soro
Hosana! Hosana!
Egbe: Eyi l'Omo nla...
3. E so fun omo binrin Sion pe
Oba re mbo wa
Hosana! Hosana!
O tenu, O si joko lori omo Ketekete
Hosana! Hosana!
Egbe: Eyi l'Omo nla...
4. Olubukun I’Eni ti mbo wa l‘oruko
Oluwa
Hosana! Hosana!
E te okan yin si ona fun Kristi
Oba Ogo
Hosana! Hosana!
Egbe: Eyi l'Omo nla Dafidi ati Oba Israeli
Ogun ketekete lo fun igbala omo
eniyan
Hosana! Hosana!
Hosana si Omo Dafidi. Amin
English »Update Hymn