HYMN 828

(FE 865)
"O si wi fun won pe, E ma to mi
Iehin” - Matt.4:19



1.  ONIGBAGBO, e wa

     Isreali t'emi

     Jesu mbebe pupopupo 

    Bi Alagbawi wa.

Egbe: E ho, e yo, f'inu didun gberin 

          Enyin 'Male ati Keferi

          E wa si 'mole.


2.  Nigbat' ojo 'dajo ba de 

     Bawo ni wo o ti wi 

     Gbat‘ o pin fun kaluku 

     Gege bi ise re.

Egbe: E ho, e yo...


3.  Nigbati nwasu nijosi 

     Iwo ko si nibe

     Mase tun wi awawi mo

     Bo sinu imole.

Egbe: E ho, e yo...


4.  E f‘Ogo fun Baba loke 

     E f‘Ogo fun Omo

     E f’Ogo fun Emi Mimo

     Metalokan lailai.

Egbe: E ho, e yo, f'inu didun gberin 

          Enyin 'Male ati Keferi

          E wa si 'mole.  Amin

English »

Update Hymn