HYMN 817
O.t.H.C 264 8.7 (FE 853)
"Gba awon enia Re la" - Ps.28:9
Tune: Baba wa orun, awa de
1. EMI ti nji oku dide
A wole niwaju Re
Na ‘wo Emi ‘ye Re si wa
Ko so gbogbo wa d‘otun
Omo Baba to d’enia
Woli, Alufa, Oluwa.
Egbe: Olugbala, Olugbala
Olugbala, gba wa la.
2. Egbe Kerubu aiye yi
E se ara nyin lokan
Egbe Serafu aiye yi
E fi okan kan sise
Ran wa lowo ka sise Re
Ka mase se aseti.
Egbe: Olugbala...
3. Ma sise l’oruko Jesu
Mase wo awon elegan
Si Matteu ori keta
W‘ese kerindilogun
Sokale ninu olanla
Sarin Egbe Serafu.
Egbe: Olugbala...
4. F’ojurere wo ‘dapo wa
F‘oro mimo Re ye wa
Fitila t’o ran sarin wa
Ma ba wa b’ororo si
Nigbat‘ ota ba sunmo wa
Jesu, jowo sunmo wa.
Egbe: Olugbala...
5. Okunkun yio b’oju orun
Isele nla y’o sise
Awon irawo y’o ma ja
Gegebi ojo ti nro
E ma jafara adura
Gbogbo enyin enia mi.
Egbe: Olugbala...
6. Nigbat’ o ba d’ojo kehin
T’omo ko ni mo baba
Ma doju ti wa l’ojo na
Gba ‘awa Egbe Serafu
Ran wa lowo ka sise Re
K’a le ma ja f'otito.
Egbe: Olugbala...
7. E f'oge fun Baba loke
E f'ogo fun Omo Re
E f'ogo fun Emi Mimo
Metalokan a juba
Ongbe re ma nghe okan wa
Fi manna orun bo wa.
Egbe: Olugbala, Olugbala
Olugbala, gba wa la. Amin
English »Update Hymn