HYMN 814

H.C 148 S.M (FE 849) 
“Emi li ona ati otito ati iye" - Matt.14:6



1.  JESU, Oto Ona 

     Mole ni t’o daju

     Gbe ese mi ailokun ro, 

     To mi s’ona tito.


2.  Ogbon at' Amona 

     Oludamoran mi 

     Ma je ki nfi O sile lai 

     Tabi ki nsako lo.


3.  Mo gb‘oju mi soke 

     Wo O, Od‘agutan

     Ki O ba le la mi l‘oye 

     K'oju mase ti mi.


4.  Nki o gba oran mi 

     Kuro ii owo Re

     Ngo simi le ‘fe rapada 

     Ngo ro m‘agbelebu.


5.  Ko mi ki nmo adun 

     Ati gbekele O

     Jo, Oluwa, mase ya mi 

     Sugbon fe mi d’opin.


6.  Mu mi la ‘danwo ja 

     De ‘le alafia;

     Si ko mi li orin titun 

     Gba mo ba di pipe.


7.  Jeki nle dabi Re

     Ki nto se alaisi

     Fi ese mi mule sinsin 

     Ki ndagba n’nu ife.


8.  Jeki nj‘eleri Re

    Gbat’ese ba run tan

    Gba okan mi ailabawon

    K’O si mu mi d’orun.  Amin

English »

Update Hymn