HYMN 797
t.s. 747 886 (FE 832) 8.8.6
"Bi o se t'emi ati iIe mi ni, Oluwa
l'awa o ma sin" - Jos 24:15
Tune: “Lehin aye buburu yi”
1. EMI at'ara ile mi
Yio ma sin Oluwa wa
Sugbon emi papa;
Yio f'iwa at'oro han
Pe mo mo Oluwa t’orun
Mo nfi toto sin.
2. Em’o f’apere ‘re le 'le
Ngo mu idena na kuro
Lodo om’odo mi
Ngo f’ise won han n’iwa mi
Sibe n‘nu ‘se mi ki nsi ni
Ola na ti ife.
3. Emi ki y’o soro gb’ipe
Emi ki y’o pe tu ninu
Om’ehin Olorun
Mo si fe je eni mimo
Ki nsi fa gbogbo ile mi
S’oju ona orun.
4. Jesu, b’O ba da ‘na fe na
Ohun elo t’iwo fe lo
Gba s’owo ara Re!
Sise ife rere n’nu mi
Ki nfi b’ onigbagbo toto
Ti ngbe l’aiye han won.
5. Fun mi l’ore-ofe toto
Nje! Emi de lati jeri
Yanu oruko Re
Ti o gba mi l’owo egbe
Ire eyi t’a mo l’okan
Ti gbogb’ahon le so.
6. Emi t’o bo lowo ese
Mo wa lati gba ‘le mi la
Ki nwasu dariji
F’omo, f’aya, f’omo-do mi
Lati mu won to ‘na rere
Lo si orun mimo. Amin
English »Update Hymn