HYMN 793
Tune: 8s 7s
“Oba ti kii ye majemu”
1. JESU nikan ni a nwasu
Jesu nikan l’a n rohin
Awa yoo gbe Jesu soke
Oun nikan l‘awa n fe ri.
Egbe: Jesu nikan Jesu nikan
Jesu nikan l’orin wa
Olugbala, Oluwosan
Oba ti n bo leekeji.
2. Jesu ni Olugbala wa,
O ru gbogbo ebi wa
Ododo Re l‘O gbe wo wa
O n s' agbara wa d’otun.
Egbe: Jesu nikan...
3. Jesu l’o n so wa di mimo
T'o n we abawon wa nu
O n segun ese at’ara
Nipa iranwo Emi.
Egbe: Jesu nikan...
4. Jesu ni Oluwosan wa
O ti ru ailera wa
Nip’agbara ajinde Re
A ni ilera pipe.
Egbe: Jesu nikan...
5. Jesu nikan l’agbara wa
Agbara Pentikosti
Joo, da agbara yii iu wa
F’Emi Mimo Re kun wa.
Egbe: Jesu nikan...
6. Jesu ni awa n duro de
A n reti ohun ipe
‘Gba t'O ba de Jesu nikan
Yoo je orin wa titi.
Egbe: Jesu nikan Jesu nikan
Jesu nikan l’orin wa
Olugbala, Oluwosan
Oba ti n bo leekeji. Amin
English »Update Hymn