HYMN 77
(FE 94)
“Ti Oluwa ni ile ati ekun re" - Ps. 24:1
1. T’OLUWA n’ile at’ekun re,
Aiye at’ekun ‘nu re,
O fi ‘di re sole lor‘okun
Ati lori ‘san omi.
Egbe: Gb’ori soke
Enyin ‘Iekun
K'a gbe nyin soke
K’Oba Ogo wole wa.
2. Tani yio g'ori oke yi lo
Ori oke Oluwa
Tani yio duro niwaju Re,
Niwaju Oluwa wa.
Egbe: Gb’ori soke...
3. Enit'o ni owo mimo
T'o si ni aiya funfun,
Ti ko gb'okan re s'oke s'asan
Ti ko si bura etan.
Egbe: Gb’ori soke...
4. Awa n‘iran ti ns'aferi Re,
Saferi Re Oluwa,
Awa yio si ri ibukun gba,
Lowo Olorun Jakob.
Egbe: Gb’ori soke...
5. A! Tani Oba Ogo yi?
Ti ‘se Oba Ogo yi?
Oluwa awon omo-ogun,
On na ni Oba Ogo.
Egbe: Gb’ori soke... Amin
English »Update Hymn