HYMN 719
L.M (FE 746)
"Kili emi of fun Oluwa” - Ps.116:12
1. KIL’O tun ye wa loni yi
Bi k’a jo k’a yo s‘Oluwa
T'o mu wa r’odun yi l’ayo
E ho, e ke halleluyah.
2. Eyi daju niti wa pe
Jesu Kristi wa larin wa
O ni k’a f’okan wa bale
Baba ko ni jek’a yan ku.
3. B’Oluwa ko ko ile na
Awon ti nko nsise lasan
B’Oluwa ko pa ilu mo
Oluso sa kan ji lasan.
4. Gbogbo Enyin asiwaju
Tesiwaju n’ise Oluwa
Baba y‘o f’agbara wo nyin
Lati segun esu at’ese.
5. Oluwa y'o dabobo wa
Olomo ko ni padanu
Agan y'o towo re b’osun
Aboyun y'o bi l'abiye. Amin
English »Update Hymn