HYMN 638

C.M.S 502, H.C 516 C.M (FE 664)
"Se igbala nisiyi, emi mbe O, Oluwa"
- Ps. 118:25



1.  OLORUN gb’okan mi loni 

     Si ma se ni Tire

     ki nma sako lodo Re mo 

     ki nma ye lodo re.


2.  Wo, mo wole buruburu

     lese agbelebu

     kan gbogbo ese mi no gi 

     Ki Krist’ j‘ohun gbogbo.


3.  F’ore ofe orun fun mi 

     Si se mi ni Tire

     Ki nle r'oju Re t'o logo 

     Ki nma sin n’ite Re.


4.  K'ero, oro, at’ise mi 

     Je Tire titi lai,

     Ki nfi gbogb’ aiye mi sin O, 

     K’iku je isimi.


5.  Ogo gbogbo ni fun Baba 

     Ogo ni fun Omo 

     Ogo ni fun Emi Mimo

     Titi ainipekun.  Amin

English »

Update Hymn