HYMN 584

H.C 309 P.M (FE 610)
"E gba ajaga mi sorun nyin..eriyin 
o si fi isinmi fun okan nyin" - Matt 11:29



1.  MO simi le Jesu 

     ‘Wo ni mo gbekele

     Mo kun fun ese at’osi 

     Tani mba tun to lo?

     Li okan aiya re nikan 

     L'okan are mi simi le.


2.  Iwo Eni Mimo! 

     Baba simi n’nu Re

     Eje etutu ti O ta 

     L’O si mbebe fun mi 

     Egun tan, mo d’alabukun 

     Mo simi ninu Baba mi.


3.  Eru ese ni mi!

     ‘Wo l'o da mi n’ide

     Okan mi si fe lati gba 

     Ajaga Re s’orun 

     Ife Re t’o gba aiya mi 

     So ‘se ati lala d’ayo.


4.  Opin fere de na 

     Isimi orun mbo

     Ese at’ irora y‘o tan

     Emi o si de ‘le 

     Ngo jogun ile ileri

     Okan mi o simi lailai.  Amin

English »

Update Hymn