HYMN 517

H.C 320 D.C.M (FE 542) 
"Kristi ninu nyin, ireti ogo"
- Kol. 1:27



1.  IFE orun, alailegbe

     Ayo orun, sokale

     Fi okan wa se ‘bugbe Re 

     Se asetan anu Re

     Jesu, iwo ni alanu

     Iwo l’onibu ife

     Fi gbala Re be wa wo 

     M‘okan eru wa duro.


2.  Wa, Olodumare, gba wa 

     Fun wa l’ore-ofe Re 

     Lojiji ni k’o pade wa 

     Ma si fi wa sile mo 

     Iwo l'a o ma yin titi

     Bi nwon ti nse ni orun 

     Iyin wa ki yio l’opin 

     A o sogo n’nu ‘fe re.


3.  Sasepe awa eda Re 

     Jek‘a wa lailabawon 

     K’a ri titobi gbala Re 

     Li aritan ninu Re

     Mu wa lat‘ogo de ogo 

     Titi de ibugbe wa

     Titi awa o fi wole 

     N‘iyanu ife, iyin.  Amin

English »

Update Hymn