HYMN 507
H.C. 300 8s 4s (FE 535)
"Oluwa ni Oluso Agutan mi"
- Ps. 23:1
1. KERUBU pelu Serafu
Ki yio si nkan
B'esu gbe tasi re si wa
Ki yio si nkan
Maikel Mimo, Balogun wa,
Y'o fo 'tegun esu tutu
Esu y’o wole lese wa
Ko le si nkan.
2. Asiwaju e ma beru
Ki y’o si nkan
Gbati Jesu wa pelu wa
Ki yio si nkan
Sa gbadura, Asiwaju
Oke nla yio di petele
Aiye ko le ri wa gbe se
Ko le si nkan.
3. Egbe Aladura mura,
Ki yio si nkan
Jesu y'o di nyin l’amure
Ki yio si nkan
E gbe ida ‘segun soke,
Kil'ohun ti mba nyin l‘eru?
Esu ko le ri wa gbe se,
Ki yio si nkan.
4. Egbe Baba nla mejila
Ki yio si nkan
Egbe F‘ogo‐Olorun-han
Ki yio si nkan
E ma foiya, e ma s’ojo
Te siwaju larin ogun
Jesu y'o fun wa n‘isegun
Ki yio si nkan.
5. Egbe Mary, Egbe Martha,
Ki yio si nkan
Egbe Dorcas, Egbe Esta
Ki yio si nkan
Korin Ogo s'Olorun wa,
E ho s‘Olorun Daniel
Halle, Halle, Halleluyah!
Ko le si nkan.
6. Egbe Akorin e mura,
Ki yio si nkan
Aladura at'Afunpe
Ki yio si nkan
Mura lati korin Mose
K'e yin Odagutan logo
K’a jumo ko Halleluyah
Ko le si nkan.
7. Kerubu pelu Scrafu
Ki yio si nkan
B‘iku npa lotun pa losi
Ki yio si nkan
Bi Shadraki Mesaki ati
Abednigo ninu ina
Ina esu ko le jo wa
Ko le si nkan.
8. Ogo ni fun Baba l’oke
Ki yio si nkan
Ogo ni fun Omo l’oke
Ki yio si nkan
Ogo ni fun Emi Mimo
Ogo ni fun Metalokan
Lagbara Olodumare
Ko le si nkan. Amin
English »Update Hymn