(FE 504) Tune: Jeka layo ninu Jesu “Emi o fe Oluwa” - Ps. 18:1 1. OLORUN ‘Wo l’agbara mi Emi o feran re Iwo l’odi at’abo mi Ni igba aini mi. 2. Ni gba ‘rora on ‘banuje Mo toro or-ofe Olorun gbo aroye mi Lat’ibi mimo Re. 3. Ati ninu ola‐nla Re O gun awon Kerubu L’apa iye afefe L’o si nfo kakiri. 4. O mu mi sibi titeju Ki nle di omnira O si pa mi mo nitori Inu Re dun simi. 5. Ona Olorun mo pupo Oro Re ye koro Awon t’o ntele ona Re Ni abo t’o daju. Amin