HYMN 461

t.C.M.S 591 S. 165 P.M (FE 486)
Ohun Orin: Oluwa emi sa ti gbohun Re
"Fi ipile re sole Iori apata" - Matt.7:25



1.  MO fi gbagbo ba Olorun mi rin 

     Ti ngo fi de ‘te ogo

     Jowo Oluwa se mi ni Tire

     K’emi r'oju rere Re. 

Egbe:  Fa mi mora, mora Oluwa

           S'ibi agbelebu t’oku 

           Fa mi mora, mora Oluwa 

           S’ibi eje Re t'o n'iye.


2.  Nin'egba mefa nin' eya Lefi 

     A f'edidi sami won, 

     Jehofa_Jire, k'O le ka wa kun 

     Awon ‘yanfe Re ‘saju.

Egbe:  Fa mi mora...


3.  Nin’Egba mefa eya Manase 

     A f'edidi sami won 

    Oluwa jowo k’a le f’edidi 

    Sami s'Egbe Serafu (Kerubu).

Egbe:  Fa mi mora...


4.  Nin’ egbe mefa eya Josefu
 
     A f 'edidi sami won 

     Jehofa-Nassi K‘O le f'edidi 

     Semi s’Egbe Kerubu (Serafu).

Egbe:  Fa mi mora...


5.  Oro Jehovah ko le lo l'ofo, 

     Oro Baba ki sai se

     Ileri t'o se fun Abrahamu

     O mu se fun Isaaki. 

Egbe:  Fa mi mora...


6.  Enia Olorun kan ko le tosi 

     Nigbati aiye ti se

     Ma je ki ebi oro at‘ale

     P’awon Egbe Serafu.

Egbe:  Fa mi mora, mora Oluwa

           S'ibi agbelebu t’oku 

           Fa mi mora, mora Oluwa 

           S’ibi eje Re t'o n'iye.  Amin

English »

Update Hymn