HYMN 354
H.C. 403 7s. 6s. (FE 377)
OJO AWON ENIA MIMO
"Titobi at iyanu ni ise Re, Oluwa Olorun
Olodumare: ododo ati otito li ona Re,
Iwo Oba awon enia mimo" - Ifi. 15:3
1. F‘AWON Ijo ti nsimi
Awa ijo t‘aiye
A f’iyin gbogbo fun o
Jesu olubukun
Oluwa, o ti segun
Ki nwon ba le segun
‘Mole ade ogo won
Lat‘odo re wa ni.
ST. ANDREW
2. A yin o fun 'ranse re
Ti o ko j’ipe re
T’o mu arakunrin re,
Wa, lati ri Kristi
Pese okan wa sile,
K‘a s‘ona lodun yi,
K‘a m‘awon ara wa wa
Lati ri bibo Re.
ST. THOMAS
3. A yin O, fun ‘ranse Re
T'isiyemeji re,
F'ese ‘gbagbo wa mule
T'o so fi ‘fe Re han
Oluwa, f ’alafia
F’awon ti nreti Re
Jek’ a mo O lotito
L‘enia at’ Olorun.
ST. STEFANU
4. A yin O, fun ‘ranse Re,
Ajeriku ‘kini
Eni, ninu wahala
T‘o nkepe Olorun
Oluwa, b’o ba kan wa,
Lati jiya fun O
L’aiye, je k‘a jeri Re,
L’orun, je k'a gb’ade.
ST. JOHANU ONIHINRERE
5. A yin O, fun ‘ranse Re,
L'erekusu Patmo
A yin O, f’eri toto
Ti o je nipa Re
A yin O fun iran na
Ti o fi han fun wa
A o fi suru duro
K’a le ka wa mo won.
OJO AWON OMO...TI A PA
6. A yin O, f'awon ewe
Ajeriku mimo
A si mimo
A si won l‘owo ogun
Lo sibi isimi
Rakelieli, ma sokun mo
Nwon bo lowo ‘rora
F’okan ailetan fun wa
K‘a gb‘ade bi tiwon.
IYIPADA TI ST. PAUL
7. A yin O, fun imole
At'ohun lat’orun
A si yin O, fun iran
Ti abinuku ri
Ati fun ‘yipada re
A fi ogo fun O
Jo, tan ina Emi Re
Sinu okunkun wa.
ST. MATTIA
8. Oluwa, lwo t’o wa
Pel'awon t’o pejo
lwo t’o yan Mattia
Lati ropo Juda
A‘mbe O, gba Ijo Re
Lowo eke woli
Rant‘ileri Re, Jesu
Pelu ‘jo Re dopin.
ST. MARKU
9. A yin O fun ‘ranse Re,
T‘lwo f'agbara fun
Enit’ ihinrere Re,
Mu orin ‘segun dun
Ati n’nu ailera wa,
Jo je agbara wa
Je ka s‘eso ninu Re,
lwo Ajara wa.
ST. FILIPPI ATI ST. JAKOBU
10. A yin O fun ‘ranse Re,
Filippi amona
Ati f‘arakonrin Re,
Se wa l'arakorin
Masai je k‘a le mo O,
Ona, lye, Ooto
K'a doju ko idanwo
Titi ao fi segun.
ST. BARNABA
11. A yin O, fun Barnaba,
Eni't ife re mu
K‘o ko ‘hun aiye sile
K'o wa ohun orun
Bi aiye ti n gbile si,
Ran emi Re si wa
Ki itunu Re toto
Tan bo gbogbo aiye.
ST. JOHANU BAPTISTI
12. A yin O f’Onibaptis,
Asaju Oluwa
Elija toto ni ‘se
Lati tun ona se
Woli to ga julo ni
O ri owuro Re
Se wa l'alabukun fun,
Ti nreti ojo re.
ST. PETERU
13. A yin O, fun‘ranse Re;
Ogboiya ninu won
O subu nigba meta
O ronupiwada
Pelu awon alufa
Lati toju agbo
Si fun won ni igboiya
At’itara pelu.
ST. JAKOBU
14. A yin O, fun ‘ranse re
Eniti Herod pa
O mu ago iya Re
O mu oro Re se
K’a ko iwara sile
K’a fi suru duro
K’a ka iya si ayo
B'O ba fa we mo O.
ST. MARTOLOMEU
15. A yin O, fun ‘ranse Re
Eni oloto ni
Enit’oju Re ti ri
Labe ‘gi opoto
Jo, se wa l’ailetan
lsraeli toto
Ki O le ma ba wa gbe
K'O ma bo okan wa.
ST. MATTEU
16. A yin O, fun‘ranse re,
T'o so ti ibi Re;
To ko‘hun aiye sile
T’o yan ona iye
Jo, da okan wa nide
Lowo ife owo
Je ka le je ipe Re
K'a nde ka tele O.
ST. LUKU
17. A yin O, f'onisegun
Ti ihinrere re
Fi O han b’Onisegun
At‘Abanidaro
Jo, f'ororo iwosan
Si okan gbogbo wa,
At' ikunra ‘yebiye
Kun wa nigbagbogbo.
ST. SIMONI ATI ST. JUDA
18. F’awon iranse Re yi
A yin O, Oluwa
Ife kanna l’o mu won
Lati gb’ona rnimo
Awa iba le jo won
Lati gbe Jesu ga
Ki ife so wa sokan
K'a de ibi isimi.
IPARI (GENERAL ENDING)
19. Apostle, Woli, Martyr
Awon egbe mimo
Nwon ko d'ekun orin won
Nwon wo aso ala
F’awonyi t'o ti koja
A yin O, Oluwa;
A o tele ipase won
A o si ma sin O.
20. lyin f'Olorun Baba
At‘Olorun Omo
Olorun Emi Mimo
Metalokan Mimo
Awon ti a ra pada,
Y‘o teriba fun O
Tire l'ola, at’ipa
At’ogo, Olorun. Amin
English »Update Hymn