HYMN 350
(FE 373)
C.M.S 577, H.C 391 tabi A. & M
396 8s. 7s
"Jerusalemu Mimo" - lfihan 21:10
1. SALEM t'orun ilu ‘bukun
T'okun fun ‘fe at'ayo
Ti af’okuta aye ko
Ni orun giga loke
Pel’ogun angeli yika
Ton nsokale b’iyawo.
2. Lat'ode orun lohun wa,
L’o ti wo aso ogo
To ye eniti o fe o
Ao sin o f'oko re
Gbogbo ita at’odi re
Je kiki oso wura.
3. Ilekun re ndan fun pearli
Nwon wa ni sisi titi
Awon oloto wo ‘nu re
Nip’ eje Olugbala
Awon to fara da ‘ponju
Tori oruko Jesu.
4. Wahala at’iponju nla
L’o s'okuta re lewa
Jesu papa l'Eni to won,
S’ipo ti o gbe dara
Ife inu Re san ni pe
K'a le s’afin Re loso.
5. Ogo at'ola fun Baba
Ogo at’ola fun Omo
Ogo at’ola fun Emi
Metalokan titi lai
At’aiyeraiye okanna,
Bakanna titi aiye. Amin
English »Update Hymn