HYMN 349
H.C227D.75(FE372)
"A gbe e soke awosanma si gba a
kuro l’oju won" - Ise 1:9
1. O ti lo, Awosanma
Ti gba kuro loju wa
Soke orun nibiti
Oju wa ko le tele
Oti kuro l’aiye yi
O ti de ibi mimo
Lala at’irora tan
lja tan, O ti segun.
2. O ti lo, Awa si wa
L’ aiye ese at'iku
A ni ‘se lati se fun
L’aiye t’o ti fi sile
K’a si tele ona Re:
K’a tele tokantokan
K’a s’ota re di ore
K'a fi Kristi han n'iwa wa.
3. O ti lo, On ti wipe
"O dara ki Emi lo"
Ni ara sa l’o ya wa
Sugbon or'ofe Re wa
On ni awa ko ri mo
A ni Olutunu re
Emi Re si je tiwa
On ns’agbara wa d‘otun.
4. O ti lo, L’ona kanna
K‘o ye k‘ljo Re ma lo
K'a gbagbe ohun ehin
K’a si ma te si waju
Oro re ni ‘mole wa
Titi de opin aiye
Nibiti oto Re wa
Y‘o pese fun alaini.
5. O ti lo, Lekan si i,
A o tun f’oju wa ri
O wa b’o ti wa l’aiye
Gege b‘o ti wa l’aiye
N'nu bugbe t‘o wa nibe
Y‘o pese aye fun wa
Ninu aiye ti mbo wa,
A o j'okan pelu Re.
6. O ti lo, Fun ire wa
Eje a duro de
Ojinde, ko si nihin
O ti goke re orun
Je k‘a gb'okan wa soke
Sibiti Jesu ti lo
Si odo Olorun wa,
Nibe l’alafia wa. Amin
English »Update Hymn