HYMN 347
t.H.C 99 10s (FE 370)
"Emi nlo, 'lati pese aye sile fun
nyin" Jn.14:2
1. E gbo iro orin ayo orun
Orin ayo ti isegun Jesu
Gbogbo ota l'o teri won ba
fun Ese, iku, isa-oku pelu.
2. O se tan lati lo gba ijoba
Fun Baba, Olorun ohun gbogbo
O se tan lati lo gba iyin nla
T‘o ye Olori-ogun ‘gbala wa.
3. Ohun ikanu ni lilo Re, fun
Awon ayanfe omo-ehin Re
E mase konnu l'oro itunu
"Emi nlo pese aye nyin sile"
4. Orun gba lo kuro lehin eyi
Awosanma se Olugbala mo
Awon Ogun-orun ho fun ayo
Fun bibo Kristi Oluwa ogo.
5. E mase ba inu nyin je rara
Jesu, ireti wa, yio tun wa
Yio wa mu awon enia re lo
Sibiti nwon o ba gbe titi lai. Amin
English »Update Hymn