HYMN 323
H.C 207 11s (FE 346)
"Mo si ni omo‐isika prun apadi
ati ti iku lowo” - lfi.1:18
1. "KABO, ojo rere,"
l'ao ma wi titi
A sete ‘ku loni,
orun di tiwa
‘Wo Oku d'alaye,
Oba tit' aiye!
Gbogb‘eda Re Jesu,
ni nwon njuba Re.
Egbe: Kabo, ojo rere, l'ao ma wi titi
A sete ku loni, orun di ti wa.
2. Eleda, Oluwa, Emi alaye
Lat'orun l'oti bojuwo
sina wa
Om'Olorun papa ni Wo
tile se
K’ O ba le gba wa la,
O di enia.
Egbe: Kabo, ojo rere...
3. 'Wo Oluwa iye, O wa to
'ku wo
Lati f'ipa Re han, O sun
n‘iboji
Wa, Eni Oloto, si m‘oro
Re se
Ojo keta Re de, jinde
Oluwa!
Egbe: Kabo, ojo rere...
4. Tu igbekun sile, t' E su de l'ewon,
Awon t'o si subu, jo gbe
won dide
F'ojurere Re han: jek' aiye riran
Tun mu 'mole wa de
'Wo sa ni 'mole.
Egbe: Kabo, ojo rere, l'ao ma wi titi
A sete ku loni, orun di ti wa. Amin
English »Update Hymn