HYMN 318

C.M.S. 217 H.C 203 8.7.8.3 (FE 341)
“Yio te mi l'orun nigbati mo ba ji 
I'aworan Re" - Ps. 17:15



1.  L‘OWURO ojo Ajinde 

     T‘ara t'okan yio pade 

     Ekun, kanu on irora 

     Y'o dopin.


2.  Nihin nwon ko le sai pin ya, 

     Ki ara ba le simi

     K’o si fi idakeroro

     Sun fonfon.


3.  Fun ‘gba die era are yi

     L’a gbe s‘ibi ‘simi re 

     Titi di imole oro

     Ajinde.


4.  Okan t’o kanu nisiyi 

     T’o si ngbadura kikan 

     Y’o bu s'orin ayo l'ojo Ajinde.


5.  Ara at’okan y’o dapo 

     Ipinya ko ni si mo

     Nwon o ji l’aworan Krist’ ni 

     ‘Telorun.


6.  A! ewa na at'ayo na 

     Y’o ti po to Ajinde! 

     Y'o duro b‘orun at’aiye 

     Ba fo lo.


7.  L'oro ojo Ajinde wa, 

     ‘Boji y’o m'oku re wa 

     Baba, iya, omo, ara 

     Y'o pade.


8.  Si dapo ti o dun bayi

     Di Jesu, masai ka wa ye 

     N'nu ‘ku dajo, k‘a le ro 

     M'a Gbelebu.  Amin

English »

Update Hymn