HYMN 298

H.C 191 8s. 7s (FE 319) 8787
"Koju si mi ki a si gba nyin la”
 - Isa 45:22



1.  WAKATI didun ni fun mi 

     Ni wiwo agbelebu

     Nibe Jesu fun mi n’iye

     ‘Lera at'alafia.


2.  Nihin l'emi o gbe joko

     Lati wo isun eje

     Eyiti y‘o we okan mi

     K'Olorun ba le gba mi.


3.  Niwaju agbelebu Re

     L’emi o ba buruburu

     ‘Gbati emi bari ‘yonu nla 

     T’o farahan loju Re.


4.  lfe ati omije mi

     Ni ngo fi we ese re

     Tori mo mo pe iku Re 

     Y’o mu iye wa fun mi.


5.  Oluwa, jo gba ebe mi,

     Se okan mi ni Tire

     Tit’ emi o fi ri ‘gbala 

     At'oju Re n'nu ogo.  Amin

English »

Update Hymn