PB 62 CMS 98 (FE 252) “Nje Oluwa ni yi ma se Olorun mi” - Gen. 28:21 1. OLORUN Betel, eniti O mbo awon Tire Enit’o mu baba wa la Ojo aiye won ja. 2. A mu eje, at’ebe wa Wa iwaju ‘te Re Olorun awon Baba wa Ma je Olorun wa. 3. Ninu idamu aiye yi Ma toju ipa wa Fun wa ni onje ojo wa At’aso t'o ye wa. 4. Na ojiji ‘ye Re bo wa Tit’ajo wa o pin Ati ni ‘bugbe Baba wa Okan wa o simi. 5. Iru ibukun bi eyi L’a mbere lowo Re Iwo o je Olorun wa, At’ipin wa lailai. Amin