HYMN 223

C.M.S. 92 H.C. 279 C.M (FE 242) 
“Olorun, Iwo Ii o ti nse ibujoko wa 
lati irandiran" - Ps. 90:1



1.  OLORUN t’odun t’o koja 

     Iret’eyi ti mbo

     Ib’isadi wa ni iji

     At’ile wa lailai.


2.  Labe ojiji ite Re,

     L’ awon enia Re ngbe! 

     Tito l‘apa Re nikansoso 

     Abo wa si daju.


3.  K’awon oke k’o to duro 

     Tabi k’a to d’aiye 

     Lailai Iwo ni Olorun 

     Bakanna, ailopin.


4.  Egbegberu odun l’oju Re, 

     Bi ale kan l’ori

     B’iso kan l’afemojumo 

     Ki orun k’o to la.


5.  Ojo wa bi odo sisan

     Opo l’o si ngbe lo

     Nwon nlo, nwon di eni’gbagbe 

     Bi ala ti a nro.


6.  Olorun t'odun t'o koja 

      Iret'eyi ti mbo

      Mas‘abo wa ‘gba 'yonu de, 

      At'ile wa lailai.  Amin

English »

Update Hymn