HYMN 198
(FE 217) Tune: 7.6.7.6.7.6.7.6.
“Imole na si nmole" - John 1:5
1. A YIN O, Baba orun
T'O ran ‘mole w‘aiye
Lati wa tan ‘mole Re;
Si okunkun aiye
Angeli nkorin wipe
Ogo f’Oba t'a bi
Ni ilu nla Dafidi
Ti nse Krist' Oluwa.
2. K'eda aiye ko gberin
K'eda orun gberin
S’Omo Mimo Dafidi
Omo ti Ileri
Yin Omo Alade nla
Ade alafia
K’ibukun ojo oni
Ko kari gbogbo wa.
3. O wa ninu irele
Lati ko wa leko
K’a tele ‘pa ese Re
Ka le gba ‘leri Re
Gbo, eda orun nkorin
Iyin f’OIugbala
Alafia l'aiye yi
Baba ba wa laja.
4. O to igbekun sile
O so wa di Tire
K'a ma d'eru ese mo
K‘a d‘eni igbala
lyin, Ola, Agbara,
Ni fun baba loke
Ogo ni fun Omo Re
Ni fun Emi Mimo.
5. Kembu on Serafu
So fun araiye pe
Ijoba ku si dede
Ijoba Olorun
‘Gba Jesu y’o tun w'aiye
Bi Onidajo Nla
K’a le fi ayo pade Re
Baba, gbo ebe wa. Amin
English »Update Hymn