HYMN 165
8.7 (FE 184)
“Tani enyin o ha fi Olorun wa?”
- Ise 40:25
1. OLUWA Agbara fohun
Bi ara loke Sinai
Awon Angeli gbohun Re,
Nwon si gbon fun iberu.
Egbe: lpe ndun, Angeli ho
Halleluya! l’orin won
O npada bo ninu ogo
Lati wa gba ijoba.
2. Jesu Oluwa mbo wa,
E jade lo pade Re
Opo yio kun fun ayo
Opo fun ibanuje.
Egbe: lpe ndun...
3. OJO ‘binu, ojo eru
T'aiye t‘orun yio fo-lo
Kini elese yio se
Le yoju ni ojo na?
Egbe: lpe ndun...
4. Adun aiye ti buse
Mura, Egbe Serafu;
Olukore fere de,
Alikama ni tire.
Egbe: lpe ndun...
5. Mase gbekele aiye
Ore aiye a fo lo
Enit‘o gb’aiye m‘aiya
Y'o gun s’ebute ofo.
Egbe: lpe ndun...
6. Oluwa m‘awon Tire
O ti se won l’ayanfe
Awon ti ko sin Jesu
Ni yio jebi nikehin.
Egbe: lpe ndun...
7. ‘Gbat'ipe ‘kehin ba dun
Jewo wa Oba Ogo
Nipa ore-ofe Re
Ki a le ba O gunwa.
Egbe: lpe ndun, Angeli ho
Halleluya! l’orin won
O npada bo ninu ogo
Lati wa gba ijoba. Amin
English »Update Hymn