HYMN 149

6.6.6.6.8.8



1.  BABA, Eleda wa, 

     Gbo orin iyin wa 

     L’ aye ati l’orun 

     Baba Olubukun: 

     Iwo l’ogo ati iyin 

     Ope, ati ola ye fun.


2.  ‘Wo Olorun omo, 

     T’ O ku lati gba wa 

     Eni t’O ji dide

     Ti O si goke lo: 

     Iwo l’ogo, ati iyin 

     Ope, ati ola ye fun.


3.  Si O Emi Mimo, 

     Ni a korin iyin 

     Iwo t’o f ’imole 

     Iye si okan wa

     Iwo l’ogo, ati iyin 

     Ope ati ola ye fun.


4.  Mimo, mimo, mimo 

     N’iyin Metalokan

     L’ aye ati l’orun 

     L'a o ma korin pe

     Iwo l’ogo, ati iyin 

     Ope ati ola ye fun.  Amin

English »

Update Hymn