HYMN 115
C.M.S.556. H.C.564 C.M (FE 132)
“Kili emi o fi fun Oluwa, nitori
gbogbo ore Re si mi?" - Ps. 116:12
1. FUN anu to po b'iyanrin
Ti mo ngba l’ojumo
Lat' odo Jesu Oluwa
Ki emi o fi fun?
2. Kini ngo fi fun Oluwa
Lat‘ inu okan mi
Ese ti ba gbogbo re je
Ko tile ja mo nkan.
3. Eyi l'ohun t'emi o se
F'ohun to se fun mi
Em' o mu ago igbala
Ngo kepe Olorun.
4. Eyi l‘ope ti mo le da
Emi osi, are
Em' o ma soro ebun Re,
Ngo si ma bere si.
5. Emi ko le sin b'o ti to
N ko n'ise kan to pe;
Sugbon em'o sogo yi pe,
'Gbese ope mi po. Amin
English »Update Hymn